15882. Gbo Okan Mi, Bi Angeli Ti Nkorin

1 Gbo okan mi, bi angeli ti nkorin
Yika orun ati yika aiye
E gbo bi oro orin won ti dun to
Ti nso gbati ese ki y’o si mo.

Egbe:
Angeli Jesu, angel’ mole
Nwon nkorin ayo pade ero lona

2 B’a si ti nlo, bee l’a si ngo orin won
Wa, arale, Jesu l’o ni k’e wa
L’okunkun ni a ngo orin didun won
Ohun orin won ni nfonahan wa [Egbe]

3 Ohun Jesu ni a n gbo l’ona rere
Ohun naa ndun b’agogo y’aye ka
Egbegberun awon t’o gbo ni si mbo
Mu won w’odo Re, Olugbala wa [Egbe]

4 Isimi de, lehin ise on aare
Ojumo mo, lehin okun aye;
Irin ajo pari, f’awon alare
Nwon si ti d’orun ibi isimi: [Egbe]

5 Ma korin nso eyin angeli rere
E ma korin didun k’a ba ma gbo;
Tit’ao fi nu omije oju wa nu
Ti a’o si ma yo titi lailai. [Egbe]

Text Information
First Line: Gbo okan mi, bi angeli ti nkorin
Title: Gbo Okan Mi, Bi Angeli Ti Nkorin
English Title: Hark! hark, my soul, angelic songs are swellling
Author: Frederick W. Faber
Translator: Anonymous
Refrain First Line: Angeli Jesu, angel’ mole
Meter: 11.10.11.10 refrain
Language: Yoruba
Copyright: Public Domain
Tune Information
Name: PILGRIMS
Composer: Henry Thomas Smart
Meter: 11.10.11.10 refrain
Key: E Major
Copyright: Public Domain



Media
Adobe Acrobat image: PDF
MIDI file: MIDI
Noteworthy Composer score: Noteworthy Composer Score
More media are available on the tune authority page.

Suggestions or corrections? Contact us